Oro Pataki!

E kaale, eyin eniyan mi gbogbo, nibi gbogbo ibi ti
owoja oro mi yii ba de. Emi omo yin ati ore yin,
Fábùsólá Tópé Ōlátúndé Christiansen naa lo n ki
yin t'oyaya t'oyaya. Imoran pataki kan ni mo ni
fun
gbogbo obinrin, paapaa obinrin ile Kaaro-Oojiire.
Mo ri ibeere kan ka ni bii iseju die seyin. Ibeere
naa
lo bakan bayii:

Se o b'oju mu fun omo obinrin ko enu ife si
okunrin. Bi Lagbaja se n so nkan, ni Tamedu so
omin. Lakasegan naa ko gbeyin. Mo wa roo wipe
ohun ti o tona ni pe ki n ba awon eniyan mi soro.
Idahun temi ree ni soki. Se awon agba bo, won ni
soki bayii ni obe oge:
Asa ati ise ti a n paro mo lo mu wa wa nibi ti a
wa
yi. Awon Agba bo, won ni san-an bayii la n rin;
Aje
nii mu ni p'ekoro. Sebi eyin naa ri bi awon Oyinbo
se n gboro si ni gbogbo ona. Nigba ti Obinrin
Omoluwabi nife Okunrin gidi, ti o n fipamo, se o
ti
gbagbe pe ki n se oun nikan lo ri Okunrin naa. Ti
okunrin naa ba bo mo elomiran to ni nkan se lowo,
Obinrin naa yo maa wo pako bi ori eran. Hehehe!
Ose die seyin ni a se Ayajo awon obinrin wa. Ohun ti o ba wu
yin,
e tete mu, ki won to gba mo yin lowo. E ranti pe,
Igi
to to kan bayii, ki n pe ninu igbo. Sugbon o, se bi
o
ti mo o, Elewa sapon. Awon agba lo so be. Emi
ko
p'owe o. E je n da'to mi nibiyii. Ilo ya, Onibode
Apomu. Aji'bela naa se die l'ole. Emi omo yin ati
ore yin naa ni, Fábùsólá Tópé Ōlátúndé
Christiansen. Mo n'ife yin. E mase sun'ra ki lati je
ki
awon eniyan yin s'alabapin ninu oro nla yii. E
pin. E
fon. Bi o ba se wu yin. A o se ori ire o. O daaro.
Ka
ji s'aye!
--
Fabusolatope
FABUSOLA TOPE CHRISTIANSEN